Àwọn Iṣẹ́ FinAfrica Investment Limited (Chinmark Group) Tí a tẹ̀ jáde: December 25, 2021
Àfiyèsí Securities and Exchange Commission, Nigeria (“SEC”) ti tọ́ sí àwọn iṣẹ́ olùṣiṣẹ́ ọjà olú-owó tí kò ní àṣẹ (FINAFRICA INVESTMENT LIMITED). Ilé-iṣẹ́ náà sọ pé ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ ìdókòwò tó ń ṣe ìdàgbàsókè ìṣòwò ní àwọn ẹ̀ka ìṣòwò ọrọ̀-ajé, tó sì ń lo owó náà nínú àwọn ilé-iṣẹ́ lábẹ́ Chimark Group.

Ìgbìmọ̀ náà fi tó gbogbo ènìyàn tó ń dókòwò létí pé FINAFRICA INVESTMENT LIMITED tàbí Chimark Group kò forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ SEC, bẹ́ẹ̀ ni SEC kò fún ètò ìdókòwò tí àwọn ilé-iṣẹ́ wọ̀nyí ń polongo ní àṣẹ.
Nítorí èyí, a KÌLỌ̀ fún gbogbo ènìyàn pé ẹni èyíkéyìí tó bá bá ilé-iṣẹ́ tí a dárúkọ yìí ṣe ìṣòwò tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjà olú-owó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ewu tirẹ̀.
FỌWỌ́ SÍ I
ÌṢÀKÓSO